Àtúpalẹ̀ Ṣaworoidẹ láti ọwọ́ Akínwùmí Ìṣọ̀lá

Ṣaworoidẹ jẹ́ àròsọ ọlọ́rọ̀ geere tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùmí Oròjídé-Ìṣọ̀lá kọ nípa àdéhùn tó wà láàrin àwọn ará ìlú kan àti àwọn ọba wọn; ojúṣe àwọn ọba sí àwọn tí wọ́n ń darí.

2
Advertisement

Ṣaworoidẹ jẹ́ ìtàn àròsọ ọlọ́rọ̀ geere tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùmí Oròjídé-Ìṣọ̀lá kọ nípa àdéhùn tó wà láàrin àwọn ará ìlú kan àti àwọn ọba wọn; ojúṣe àwọn ọba sí àwọn tí wọ́n ń darí.

Olóògbé Akínwùmí Ìṣọ̀lá

Jogbo tó jẹ́ ìbùdó ìtàn náà ni o ṣe atọ́ka sí orílẹ̀-èdè bíi Nàìjíríà níbi tí àwọn olórí tàbí adarí ti máa ń kó àdéhùn tí wọ́n ṣe fún ará ìlú láti sìn wọ́n dáadáa jẹ.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùmí Ìṣọ̀lá kọ́kọ́ kọ ìtàn yìí fún fíìmù Ṣaworoidẹ tí ọ̀jìnmì àti ogbóǹtarìgì aṣefíìmù, Alàgbà Túndé Kèlání, gbé jáde ní ọdún 1999.

Advertisement
Fíìmù Ṣaworoidẹ

Ọ̀jọ̀gbọ́n Ìṣọ̀lá padà gbé ìwé kan jáde ní ọdún 2008 pẹ̀lú ilé ìṣẹ́ agbéwèjáde, “University Press PLC,” tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Ṣaworoidẹ.

Ìwé Ṣaworoidẹ

Ìwé náà ṣe àfihàn ìwà olè, jẹgúdújẹrá, tembelekún, ìmọ-tara-ẹni-nìkan, “àti bó ba a, o pa à” tí ó kún ọwọ́ àwọn olóṣèlú. Tí kò bá sí ohun tó kó wọ́n ní ìjanu, wọ́n á máa ṣe bí ó ṣe wù wọ́n. Ìlú kò ní fara rọ. Ìyà á jẹ àwọn ará ìlú.

Ní ọdún 2022, Ọ̀jọ̀gbọ́n Pamela J. Olúbùnmi Smith ṣe aáyan ògbufọ̀ Ṣaworoidẹ si èdèe Gẹ̀ẹ́sì pẹ̀lú àkọlé titun, The Brass-Bells Drum.

Ṣaworoidẹ ati The Brass-Bells Drum

Ìbùdó Ìtàn

Ìbùdó ìtàn Ṣaworoidẹ ni ìlú Jogbo, ìlú afinúdá kan ni gúúsù Nàìjíríà. Àwọn olùdásílẹ̀ ìlú yìí ṣẹ̀ wá láti Ọ̀yọ́-Ilé nígbà tí Ọ̀yọ́-Ilé tú.

Àbùdá ìlú Jogbo ṣe atọ́ka sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Bíi Nàìjíríà, Jogbo ní ohun àlúmónì àmúsọrọ̀. Àwọn olùsakoso Jogbo àti àwọn agégẹdú òkèèrè ń ni àwọn aráàlú lára pẹ̀lú bí wọ́n se ń dí iṣẹ́ òjọ́ wọn lọ́wọ́.

Ìhùwàsí àwọn olóṣèlú, ológun, agégẹdú àti àwọn aráàlú Jogbo kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí ti Nàìjíríà.

Ìsọnísókí Ìtàn

Àdéhùn kan wà láàrin àwọn aráàlú Jogbo àti gbogbo ọba tó bá jẹ ní ìlú Jogbo. Àdéhùn yìí ni kìí jẹ́ kí àwọn ọba Jogbo lówó lọ́wọ́ bíi àwọn ọba ibòmíràn. Ohun tí wọ́n fi ṣe atọ́ka àdéhùn yìí ni ìlù Ṣaworoidẹ ati adéidẹ. Ewu ńlá wà níbi àìṣe ìṣàkóso ìlú dáadáa àti lílu owó ìlú ní pónpó.

Nígbàa ti Ọba Lápitẹ́ ni nǹkan bẹ̀rẹ̀ sì ní dàrú. Lápitẹ́, torí pé ó fẹ fi ipò ọba kó owó ìlú sí àpò tara rẹ̀, kọ̀ jálẹ̀ láti sín ‘bẹ́rẹ́ ìbura. Ó lo ọgbọ́n àyínìke láti gun àpèrè ọba.

Kínni ó di ọba sí, ṣe ló ṣètò bí àwọn agbénipa ṣe dá ẹ̀mí Adébòmí tí wọ́n jọ du ipò ọba légbodò. Àwọn agbénipa pa Adébòmí tòun tìyàwó rẹ̀.

Lápitẹ́ tún rán àwọn ọlọ́pàá láti gbé Àyàngalú tí ìṣàkóso ìlù Ṣaworoidẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n Àyàngalú, Àyànníyì àti ọmọ Adébòmí (tí ṣe ọmọ-ọmọ Àyàngulú) rápálá sálọ kúrò nílùú fún Lápitẹ́.

Ìdí tí Ọba Lápitẹ́ fi mú gbogbo àwọn tó rí gẹ́gẹ́bí alátakò kúrò nílẹ̀ nipé ẹ̀rù àtúnbọ̀tán àìsínbẹ́ẹ́rẹ́ rẹ̀ ń bà á. Nígbà tí ó ti ríi pé kòsí alátakò mọ́n, ó bẹ̀rẹ̀ sì ní jẹ ayé-fàmí-létè-n-tutọ́.

Lápitẹ́ dàyà dé owó ìlú; òun àti àwọn olóyè ń ṣe owó àwọn aráàlú Jogbo bó ṣe wù wọ́n.

Ara ń ni aráàlú. Àmọ́ Ọba Lápitẹ́ wẹ̀wù kòkàn-mi; ó dá agbádá “bámú-bámú ni mo yó, èmi ò mọ̀n pé ebi ń pa ọmọ ẹnìkọ́ọ̀kan.”

Àwọn aráàlú fi ẹ̀hónú wọn hàn-án ní gbogbo ọ̀nà. Wọ́n bá a sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀; wọ́n bá a sọ̀rọ̀ ní gbangba.

Nígbà tó hàn gbangba-gbàngbà pé ó ti fi òwú elépo dí etí àti ojú rẹ̀ sí ẹ̀hónú àti ìpèníjà àwọn aráàlú, àwọn ọ̀dọ́ Jogbo wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi s’àdá; wọ́n gbéná w’ojú àwọn agégẹdú tí wọ́n ń fi tiwọn dí ti àwọn àgbẹ̀, apẹja, àti ọdẹ lọ́wọ́.

Àwọn ọ̀dọ́ ajìjàgbara náà kò ya Lápitẹ́ sọ́tọ̀. Wọ́n jí adéidẹ rẹ̀ gbé pẹ̀lú èróngbà pé tí adéidẹ náà bá pẹ́ níta kọjá bóṣeyẹ lọ, Ọba Lápitẹ́ máa fi ipò ọba sílẹ.

Ṣùgbọ́n Ọba Lápitẹ́ kò ṣetán láti fi ipò ọba sílẹ̀. Torí náà, ó pàtọ̀pọ̀ pẹ̀lú àwọn agégẹdú fún ìrànwọ́ bí wọ́n ó ṣe ṣe àwárí adé tí àwọn ajìjàgbara jí gbé.

Ọ̀gágun Làgàta tó jẹ́ olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ àbò fún àwọn agégẹdú ló kó ìkọ ọmọ ogun sòdí láti gba adéidẹ lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jí i gbé. Làgàta ṣẹ́gun àwọn ọ̀dọ́ ajìjàgbara; ó sì dá adéidẹ padà fún Lápitẹ́.

Níbi ayẹyẹ àṣekágbá dídá adéidẹ padà ni Ọ̀gágun Làgàta tòun tàwọn ọmọ ogun rẹ̀ ti fi ipá gba ìjọ́ba lọ́wọ́ Lápitẹ́. Wọ́n tún fi ẹ̀mí Lápitẹ́ ṣòfò dànù.

Làgàta ṣàlàyé pé nítorí ìyà tí Lápitẹ́ fi ń jẹ aráàlú àti ìwà jẹgúdújẹrá Lápitẹ́ àti àwọn olóyè rẹ̀ lòun ṣe gba ìjọba lọ́wọ́ Lápitẹ́.

Àmọ́ ìjọba Làgàta náà kò sunwọ̀n fún aráàlú. Àwọn ẹ̀sùn tó tì sọ́rùn Lápitẹ́ lòun gan mú ní ìbádà. Òun ti Olóyè Balógun àti Olóye Séríkí ń ṣe owó ìlú àti ìṣàkóso ìlú básubàsu.

Ṣùgbọ́n èdì kò mọ ẹni aìdíì. Làgàta bá ní òun fẹ́ dé adéidẹ láti sàmì pé àwọn ológun náà ti di ọ̀kan lára ìdílé tí ipò ọba ìlú Jogbo tọ́ sí. Bíi Lápitẹ́, Ọ̀gágun Làgàta kò sín ‘bẹ́rẹ́ kankan. Bẹ́ẹ̀sini wọn ò gbọdọ̀ lu ìlù Ṣaworoidẹ ní sàkánì rẹ̀ pẹ̀lú adéidẹ lórí.

Nítorí náà, àwọn ẹ̀sọ́ àbò wá Àyàngalú kàn nínú igbó tó sálọ. Wọ́n jù ú sí àhámọ́ kí ayẹyẹ ìdé adéidẹ Làgàta baà le lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀.

Nígbà tí Làgàta dé adéidẹ sórí, ìlù Ṣaworoidẹ sọ. Lójú ẹsẹ̀ ni orí fífọ́ ti pa Ọ̀gágun Làgàta. Àyànníyì, ọmọ Àyàngalú, tí gbogbo wọn kò fojúsí ló lu ìlù Ṣaworoidẹ.

Àwọn ọ̀dọ́ ajìjàgbara pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Amawomárò àti Àyàngalú ṣe àtúntò ìlú. Wọ́n sọ Arẹ́sẹ̀jábàtà, ọmọ olóògbé Adébòmí, di ọba ìlú Jogbo.

Arẹ́sẹ̀jábàtà tẹ̀lé gbogbo orò ìbúra. Lẹ́hìn náà ni ó fẹ́ Arápáregángan, ọmọ àlè Lápitẹ́. Gbogbo ìlú sì tùbà, ó sì tùṣẹ.

Kókó-ọ̀rọ̀ Inú Ìtàn

  • Àwọn kókó-ọ̀rọ̀ nínú ìwé Ṣaworoidẹ láti ọwọ́ Akínwùmí Ìṣọ̀lá

Ẹ̀dá-ìtàn

  • Àwọn ẹ̀dá-ìtàn nínú Ṣaworoidẹ láti ọwọ́ Akínwùmí Ìṣọ̀lá

WHATSAPP: Click HERE to join the new Literature PADI WhatsApp group to receive latest updates on your phone and for further literary discussions!

Advertisement

2 COMMENTS

Comments are closed.