Àwọn ẹ̀dá-ìtàn nínú Ẹfúnṣetán Aníwúrà láti ọwọ́ọ Akínwùmí Ìṣọ̀lá

Akọni obìnrin ni Ẹfúnṣetán. Òun ni olú ẹ̀dá-ìtàn eré yìí. Ẹfúnṣetán ni ẹnìkejì tó jẹ oyè Ìyálóde Ìbàdàn nínú ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ Ìbàdàn.

0
Efunsetan Aniwura
Efunsetan Aniwura
Advertisement

Lára àwọn ẹ̀dá-ìtàn nínú eré oníṣe Ẹfúnṣetán Aníwúrà (1970) tí Akínwùmí Ìṣọ̀lá kọ lati rí Ìyálóde Ẹfúnṣetán Aníwúrà tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ àkọlé eré náà, Àjílé, Adétutù, Ìtáwuyì, Akínkúnlé, Ọ̀ṣúntúndé, Àwẹ̀ró, Akíngbadé, àti Látòósà. Àwọn ẹ̀dá-ìtàn tí mo mẹ́nubà ni ipa wọn fẹ́ ṣe pàtàkì jùlọ nínú eré náà.

Ẹ jẹ́ ká fi ojú sùnùkùn wo ipa tí àwọn ẹni-ìtàn wọ̀nyí kó nínú Ẹfúnṣetán Aníwúrà.

Ìyálóde Ẹfúnṣetán Aníwúrà

Akọni obìnrin ni Ẹfúnṣetán. Òun ni olú ẹ̀dá-ìtàn eré yìí. Ẹfúnṣetán ni ẹnìkejì tó jẹ oyè Ìyálóde Ìbàdàn nínú ìtàn ìṣẹ̀dálẹ̀ Ìbàdàn.

Advertisement

Nínú eré yìí, ònkọ̀wé fi Ẹfúnṣetán hàn gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ tí í fi àwọn ẹrú rẹ̀ dá àrà tí ó bá wù ú. Bí kò bá fi ìyà jẹ wọ́n fún ẹ̀sùn kan tàbí òmíràn, á ṣì pa wọ́n ní ìpa adìẹ fún pé wọ́n tàpa sí òfin rẹ̀.

Ẹfúnṣetán kò ní ọmọ, bẹ́ẹ̀ si ni kò fẹ́ kí ẹrúbìnrin rẹ̀ kankan lóyún, débi pé yó bimọ.

Akínwùmí Ìṣọ̀lá fi Ẹfúnṣetán Aníwúrà hàn gẹ́gẹ́ bíi ìkà pọ́nbélé. Kò sí bí ẹ ṣe bẹ̀ ẹ́ tó, t’inú rẹ̀ ni yó ṣe. Ẹ̀rí ìwà ìkà rẹ̀ wà ní ojú ewé kejìdínlógún (Ìran Kẹta) níbi tí Ayọ̀ọ́rìndé, ọ̀kan nínú àwọn ìjòyè Látòósà, ti ṣe ìrántí bí Ẹfúnṣetán ṣe pa “ọmọge mẹ́tàlá àti ọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n” ní ìdunta. Ní ojú ewé kọkànlélógún (Ìran Kẹrin), ọ̀kan lára àwọn ẹrú Ẹfúnṣetán, kin ìtọ́kasí yìí lẹ́yìn pẹ̀lú àpèjúwe bíi “àgbàrá ẹ̀jẹ̀ tí ńṣàn lágbàlá, tí orí omidan ńyì gbiiri bí orí ẹ̀ran; tí ọrùn gìrìpá wá dàbí ọ̀gẹ̀dẹ̀ lẹ́nu idà olójúméjì.”

Bi ojú wa kò bá tiẹ̀ tó ti ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìdunta, a sá rí bí Ẹfúnṣetán ṣe ní kí abẹ́nilórí gé orí Adétutù sọnù nítorípé ó lóyún.

Ní àfikún, Akínwùmí Ìṣọ̀lá fi Ẹfúnṣetán Aníwúrà hàn gẹ́gẹ́ bíi obìnrin alágbára. “Olókìkí obìnrin ni, gbajúmọ̀ sì ni pẹ̀lú” (ojú ewé kejìdínlógún). Ó ní owó, ó ní èèyàn, bẹ́ẹ̀ sì ni ó ní ògùn. Agbára ògùn tí ó ní ni kò jẹ́ kí èdì Ìtáwuyì dì í láti jẹ májèlé.

Nígbà tí tìlú-tìjòyè kò le farada ìkà àti àìbíkítà Ẹfúnṣetán, wọ́n jẹ ilé rẹ̀ run. Wọ́n sì tú àwọn ẹrú rẹ̀ sílẹ̀. Ẹfúnṣetán di ẹdun arinlẹ̀ nílé Látǒsà níbi tí ó ti gbé májèlé jẹ.

Front cover of Efunsetan Aniwura, Iyalode Ibadan
Front cover of Efunsetan Aniwura, Iyalode Ibadan

Àjílé

Àjílé ni ọ̀rẹ́ Ẹfúnṣetán. Ọ̀rẹ́ àti èwe ni àwọn méjèèjì. Ibi tí ẹ bá ti rí Ẹfúnṣetán, dandan ni kí ẹ rí Àjílé. Kódà, Ẹfúnṣetán a máa ṣe ìrànlọ́wọ́ fun Àjílé àti ọkọ rẹ̀ tí ṣe ọ̀rẹ́ Látòósà.

Àjílé ni ó wá kìlọ̀ fun Ẹfúnṣetán nípa àwọn ìjòyè àti ará ìlú tí wọ́n bọ̀ wá jẹ ilé Ẹfúnṣetán run. Àmọ́, Ẹfúnṣetán kọ etí ikún sí ikìlọ̀ yìí.

Adétutù

Adétutù jẹ́ òkan lára àwọn ẹrúbìnrin Ẹfúnṣetán Aníwúrà. Òun ni olólùfẹ́ Ìtáwuyì. Ẹfúnṣetán bẹ́ ẹ ní orí nígbà tí ó ní oyún. Ikú Adétutù páàpá kún ohun tí gbogbo ìlú fi jẹ ilé Ẹfúnṣetán run.

Ìtáwuyì

Ẹrúkùnrin Ẹfúnṣetán Aníwúrà ni Ìtáwuyì ṣe. Ọkùnrin mẹ́ta ni Ìtáwuyì. Èyí hàn gbangba nínú bí ó ṣe dá Àkànó mọ́lẹ̀ nínú ìjàkadì ni Ìran Kẹrin.

Òun ni ó fún Adétutù loyun; tí ó gbìmọ̀pọ̀ pẹ̀lú Akínkúnlé, àbúrò Ìyálòde, pé kó sọ pé òun lòún ni í, pẹ̀lú ìrètí pé Ìyálòde kò ní pa Adétutù tí ó bá mọ̀ pé Akínkúnlé ló fún-un lóyún.

Lẹ́yìn ìgbà tí akitiyan rẹ̀ láti dóòlà ẹ̀mí Adétutù pòfo, Ìtáwuyì gbìyànjú láti pa Ẹfúnṣetán. Ó fi májèlé sí inú oúnjẹ Ẹfúnṣetán. Ó sì gbìyànjú láti dì í pẹ̀lú. Nígbà tí èdì rẹ̀ kò mú Ẹfúnṣetán, Ìtáwuyì gbìyànjú láti fi àdá sá Ẹfúnṣetán pa, ṣùgbọ́n Ìyálóde fi ògùn (Gbètugbètu) láti ká ọwọ́ rẹ̀ ró, tí ó ṣì pàṣẹ fún-un láti jẹ nínú oúnjẹ tí ó fi májèlé sí. Báyìí ni Ìtáwuyì ṣe gbèkuru lọ́wọ́ ẹbọra.

Back cover of Efunsetan Aniwura, Iyalode Ibadan
Back cover of Efunsetan Aniwura, Iyalode Ibadan

Akínkúnlé

Akínkúnlé ni àbúrò Ìyálóde Ẹfúnṣetán. Ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàárín òun àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ fi hàn gedegbe pé tẹrú-tọmọ tẹbí-tará ni Ìyálòde ńwu ìwà àìbíkítà rẹ̀ sí. Ìyálóde kò torípé Akínkúnlé ló fún Adétutù lóyún dá ẹ̀mí Adétutù sí.

Bákan náà, a rí i bi Ìyálóde ṣe kanra mọ́ Akínkúnlé ní Ìran Kejì lórí pé onítọ̀hún wá dágbére fún-un pé oun fẹ́ lọ yọjú sí ọmọ òun, Délé, tí ó ńṣe àárẹ̀. Torípé kò bí ọmọ tirẹ̀, Ìyálóde rí i bíi pé ó wá fi ọmọ lá òun lójú ni.

Ọ̀ṣúntúndé

Ọ̀kan nínú àwọn ẹrúkùnrin Ẹfúnṣetán Aníwúrà ni Ọ̀ṣúntúndé jẹ́. Ọ̀rẹ́ Ìtáwuyì sì ni pẹ̀lú. Ó mọ̀ nípa bí Ìtáwuyì ṣe fi májèlé sí oúnjẹ fún Ìyálóde.

Bótilẹ̀jẹ́pẹ́ òkùnkùn ni ó wà tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ó wà lára èèyàn díẹ̀ tó mọ̀ pé Ìtáwuyì ló ni oyún inú Adétutù, kìí ṣe Akínkúnlé.

Àwẹ̀ró

Ẹrúbìnrin Ìyálóde ni Àwẹ̀ró ṣe. Òun àti Adétutù jẹ́ ọ̀rẹ́. Òun ni Ìtáwuyì rán láti fi májèlé sí inú ọbẹ̀ fún Ìyálóde. Sùgbọ́n ọwọ́ pálábá rẹ̀ ṣẹ́gi. Ẹfúnṣetán sì fi tipátipá fá ọbẹ̀ náà sí Àwẹ̀ró lẹ́nu. Èyí ni ó ṣe okùnfà ikú rẹ̀.

Akíngbadé

Akíngbadé ni ègbọ́n Ìyálóde okùnrin. Nínú eré oníṣe yìí, ó ṣe ìṣe àgbà tí kìí wà lọ́jà kí orí ọmọ tuntun wọ́. Ó kó àwọn àgbààgbà àdúgbò sòdí láti lọ bẹ Ẹfúnṣetán pé kó jèbùrẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Adétutù. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kó dárí jin Adétutù nítorípé Akínkúnlé ló ṣe aṣemáṣe.

Akíngbadé mọ̀ pé kìígbọ́-kìígbà ni àbúrò rẹ̀. Ó sì mọ̀ pé ẹja ni ọ̀rọ̀ náà. Sùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣe akitiyan tirẹ̀.

Látòósà

Ààrẹ Látòósà ni olórí àwọn ìjòyè Ìbàdàn. Òun tàwọn ìjòyè rẹ̀ ni wọ́n ṣe ìjọba Ìbàdàn. Ó kópa gidi nínú bí wọ́n ṣe ti ọwọ́ ọmọ Ẹfúnṣetán bọsọ. Ó rọ̀ ọ́ lóyè. Ó sì síwájú àwọn ilú láti jẹ ilé Ẹfúnṣetán run. Ó ṣe atọ́nà lórí i bí àwọn ẹrú Ẹfúnṣetán ṣe gba òmìnira.

Ní èdè kan, Ààrẹ Látòósà, pẹ̀lú àtílẹ́yìn àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn ará ìlú, sọ Ẹfúnṣetán di ẹni ìyà.

Further Reading:

Also in this Category:

WHATSAPP: Click HERE to join the new Literature PADI WhatsApp group to receive latest updates on your phone and for further literary discussions!

Advertisement