“Ìyí’gbà” (Time Travel) jẹ́ fíìmù àgbéléwò Yorùbá kan tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan sodo sí nínú. Ṣé ti ìhùwàsí “bó ò ba a, o pa á” àwọn ọmọ ènìyàn nínú fíìmù náà ni ká wò ni? Tàbí ti ìwa “aríjẹ nídìí màdàrú” tí ìtàn náà ṣe àfihàn rẹ̀?
Ìtàn náà dá l’órí Dokita Àlàáfíàtáyọ̀ Éégúnjẹ́nmí ti àdàpè orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Dokita Láfíà” àti àwọn àtakò tó kojú lọ́dọ àwọn aríjẹ nídìí màdàrú dókítà ẹẹ́gbẹ rẹ̀.
Àwọn dọ́kítá yìí, nítorí àpo tiwọn, nii wọ́n ń ṣe’ni, àwọn náà sì ni wọ́n sì ń gba’ni. Wọ́n á fẹ́ àwọn àjàkálẹ̀ ààrùn s’ìlú kí àwọn tó bá lùgbàdì àwọn àìsàn náà le ma wá si ilé ìwòsan aládani tiwọn.
Àmọ́ Dokita Láfíà kò bá wọn pé síbi ìbàjẹ́. Akọ́sẹ́mọsẹ́ nídi iṣẹ́ ìṣẹgun òyìnbó àti t’ìbílẹ̀ l’ọmọkùnrin tí a n sọ yìí; bẹ́ẹ̀sìni kò fi iṣẹ́ rẹ̀ jáfara rárá.
Àíjafara rẹ̀ nídìí isẹ́ ìjọba ń dí àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ní ilé ìwòsan aládani lọ́wọ́ ṣùgbọ́n tí púpọ̀ nínú wọn ń ṣiṣé pẹ̀lú ìjọba.
Wọ́n gbé ogun dìde sí. Ogun náà lo sì gbé òun, ìyàwó, àti àwọn ọmọ rẹ̀ mì bíi kàlòkalò.
Ogún ọdún lẹyìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni ọmọ emèrè kan, Tọlánikáwò Àyìnkẹ́ Oníkòyí, tí a bí lọ́jọ́ tí Dokita Láfíà kú, tí ó ń pòkàkà ikú lọ́wọ́, ṣe àwárí dókítà náà ní ọjà níbi tí aláàwé ti wà nípò àìrí.
Àwọn méjèèjì gbà láti ran ara wọn lọwọ. Ìgbà yí sí ogún ọdún sẹ́yìn tí Dókítà Láfíà ń w’iná ìṣòro láti ọ̀dọ̀ àwọn elénìní.
Àbalọ àbábọ̀ gbogbo rẹ ni ti àṣeyọrí ire lóríi ìká.
Àwótúnwò ni fíìmù “Ìyí’gbà” jẹ́. Lẹyìn ẹ̀kọ́ tó kún inú rẹ, ìlò èdè rẹ́ wú’ni lórí púpọ̀. Àwọn òṣèré inú rẹ̀ ṣẹ àmúlò èdèe Yorùbá aláìlábàwọ́n — kò sí àdàpọ̀ Yorùbá pẹlú èdèe Gẹ̀ẹ́sì. Ṣe ló dà bí kí èèyàn ma pọ́n àwọn òṣèré náà l’ẹ́nu la pẹ̀lu bí èdèe Yorùbá ṣe dán l’ẹ́nu wọn.
Àwọn òṣèré náà o kẹ̀rẹ̀ nípa lílo àkànlò-èdè, òwe, àfiwé àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Lára àwọn òṣèré tí wọ́n kó pa nínú fíìmù yìí ni Adéníyì Johnson (Dokita Láfíà), Múyìwá Adémọ́lá (Dokita Asúbíaró), Saidi Balógun (Dokita Ògùn), Adéọlá Olúsholá (Tọlánikáwò), Aishat Lawal (Ìyàwó Dokita Láfíà), Fausat Balógun (Ìyá Agbẹ̀bí) àti àwọn òṣèré mìíràn.
A gbé òsùbà káre fún àwọn tó ṣe fíìmù yìí, pàtàkì jùlọ olùdarí àti olùkọ̀tàn fíìmù yìí.
Àwọn Òwe àti Àkànlò-èdè Àrídìmú
Ẹ̀sun térétéré ní di ibú; igbó tí èèyàn ò bá fi sílẹ l’ọ́rùn ní títọ̀ ló ń d’ọ̀nà.
Bí orí fífọ́ ò bá pa’ni, tí ọrùn dídùn ò gb’ẹ̀mí èèyàn, àfojúdi lè rá’ni l’ọ́run ọ̀sán gangan.
Ọmọ tó bá sọ’lé nù, ní ṣe lọ́ so àpò ìyà kọ́.
Bí ẹni tí wọ́n ń pè kò bá gbọ́, ẹni tó ń pè é náà kò ní dákẹ́.
Àgbẹ̀ tó ti iṣu bọ́’lẹ̀ kọ́ ni ò fẹ̀ẹ́ kí iṣu ó ta, ikán tó ń bẹ nísàlẹ̀ ebè níí mú iṣu àgbẹ̀ jìn.
Ojú ò gbọdọ̀ torípé ata kéré kó kéré ata.
Kò sí ohun tí ewújù lé è fi igi òpẹ ṣe.
Ọ̀tọ̀ ni igba. Ọ̀tọ̀ ni ìgbà. Ọ̀tọ̀ ni igbá. Igba igbá ò le k’ọ́rọ̀ tó bá jábọ́ jọ. Igba ọ̀rọ̀ nìkan ló lè kó àkúfọ̀ igbá nígbà igba.
Ọmọdé tó bẹ̀rù òkùnkùn, òun ló mọ ohun tó rí. Àgbàlagbà tó ta’kùn s’ọ́nà, ti ẹ̀ náà yé e. Ká wá f’ẹ̀yìn rìn láti ibí dé ìlú Ìṣẹ́yìn, ká d’ẹyin s’ọ́wọ́ ọ̀tún, ká d’ẹyìn s’ọ́wọ́ òsì, ẹni tí ò ní yin ni ò ní yin ni.
Ohun tí ò le kò w’ọ́bẹ.
Ebè tí gúlúsọ bá fi àárọ̀ kọ, ọjọ́ alẹ́ ní tú u ká.
Àbá ni ikán ń dá. Ikán kan kò le mu òkúta.
Ìmọ̀wọn ara ẹni ló ń gbéni lékè; ó dẹ̀ ń pọ́n’ni lé.
Tí ọ̀rọ̀ bá kan òkè, tó kan ilẹ̀, ó ní ibi àá gbé e sí.
Àíwúlò ará ayé ló ń mú’ni rántí èrò ọ̀run.
WHATSAPP: Click HERE to join the new Literature PADI WhatsApp group to receive latest updates on your phone and for further literary discussions!
Èyí dáa. Ẹ má dá a dúró.
Comments are closed.